Zechariah 6:1-3

Kẹ̀kẹ́ ogun mẹ́rin tí ìdájọ́ Ọlọ́run

1 aMo sì yípadà, mo sì gbé ojú mi sókè, mo sì wò, sì kíyèsi i, kẹ̀kẹ́ mẹ́rin jáde wá láti àárín òkè ńlá méjì, àwọn òkè-ńlá náà sì jẹ́ òkè-ńlá idẹ. 2Àwọn ẹṣin pupa wà ní kẹ̀kẹ́ èkínní; àti àwọn ẹṣin dúdú ní kẹ̀kẹ́ èkejì. 3Àti àwọn ẹṣin funfun ní kẹ̀kẹ́ ẹ̀kẹta; àti àwọn adíkálà àti alágbára ẹṣin ní kẹ̀kẹ́ ẹ̀kẹrin.
Copyright information for YorBMYO